🌺ISE NI OOGUN ISE
🖊️Mura si ise ore mi
🖊️Ise ni afi ndeni giga
🖊️Bi ako ba reni fehinti
🖊️Bi ole la a ri
🖊️Bi a ko ba reni gbekele
🖊️A tera mo ise eni
🖊️Iya re le lowo lowo
🖊️Baba re si le leshin le kan
🖊️Bi o ba gboju le won
🖊️Ohun te tan ni mo so fun o
🖊️Ohun ti a ko ba jiya fun
🖊️Se kii le tojo rara
🖊️Ohun ti a ba fara sise fun
🖊️Ni npe lowo eni
🖊️Apa lara
🖊️Igunpa ni iye kan
🖊️Bi aiye ba nfe o loni
🖊️Ti o balowo lowo
🖊️Aye a ma fe o lola
🖊️Jeki o wa ni ipo atata
🖊️Aiye a ma ye o si terin-terin
🖊️Jeki o deni ti rago
🖊️Ko o ri bi aiye ti nyinmu si o
🖊️Eko si le seni doga
🖊️Mura ki o ko dara-dara
🖊️Bi o ri opo eniyan 🖊️Ti n fi eko serin rin 🖊️Dakun ma fara we won 🖊️Iya nbo fomo ti ko gbon
🖊️Ekun mbe fomo ti o nsa kiri
🖊️Ma fowuro sere ore mi
🖊️Mura si ise ojo nlo.👌🏼👍🏼